Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 678

Awon aguntan mi kin yio segbe.

Meter: 7.7.7.7.

Scripture: Jn. 10:28

1

mfTire laelae l'awa se

Baba, Olorun ife;

crJe k’aje Tire titi

L'aye yi, ati laelae.

2

mfTire laelae, l'awa se

Ma toju wa la'ye yi;

’Wo iye, Ona, Oto,

To wa si ilu orun.

3

pTire laelae: Abukun

L'awon t’ose simi won!

crOlugbala, Ore wa,

Gba 'ja wa ja de opin.

4

pTire laelae:- Jesu pa

Awon agutan Re mo,

crL'abe iso rere Re

Ni k'o pa gbogbo wa mo.

5

fTire laelae:- Aini wa

Ni o je aniyan Re;

O ti f’ese wa ji wa,

To wa si ibugbe Re.