Hymn 68
E korin titun si Oluwa; nitori O ti se ohun iyanu.
Meter: 11.11.11.11 & Ref
Scripture: OD 98:1
1
fEyin Oba Ogo, On ni Olorun,
Yin I fun ‘se ‘yanu ti O ti fi han,
O wa pel’awon ero mimo l’ona
O si je imole won l’osan l’oru
CHORUS
Eyin angeli didan lu duru wura,
Ki gbogbo nyin juba t’e nwo oju Re,
Ni gbogbo ‘joba Re, b’aye ti nyi lo,
Ise Re y’o ma yin,
Ise Re y’o ma yin,
Fi ibukun fun Oluwa okan mi
2
E yin fun ‘rapada, ti gbogbo okan,
E yin fun orisun imularapa
Fun inu rere ati itoju Re,
Fun ‘daniloju pe O ngbo adura,
3
E yin fun idanwo, bi okun ife,
T’o nso wa po mo awon ohun orun,
Fun ‘gbogbo ti nsegun ‘reti ti ki sa
Fun ile Ogo t’O ti pese fun wa.