Hymn 681
Emi fi ifeni ayeraye fe O.
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: Jer. 31:3
1
mfIfeni ayeraye,
L’ore-ofe fi fe mi,
Emi Re lat’oke wa
L’o fi oye na ye mi,
Alafia didun ni
Ti ngbe mi kuro l’aye,
Ife ti ko le tan ni,
Mo je Tire titi lae.
2
fAye di orun fun mi,
O ndun si lojojumo,
Mo nri Krist’ nibi gbogbo
Ti awon t’aye ko ri,
Ninu orin t’eye nko
Ninu itanna igbe,
Lat’igba ti mo mo pe,
Mo je Tire titi lae.
3
fOhun ti mba l’eru
Ko tun ba mi l’eru mo,
Labe iye-apa Re,
Nib’ikok’Oga ogo;
Nibe ni mo simi le;
Aniyan on ’yemeji,
Ko duro l’okan mi mo,
Mo je Tire titi lae.
4
fTire laelae l’emi se,
Tani y’o ya wa n’ipa?
Isimi wo lo to yi?
Fun okan ti Kristi ngbe;
B’orun on aye koju,
Ti ogo re si parun,
T’emi t'Olorun y’o wa.
Mo je Tire titi lae.