Hymn 684
Ki a si pa emi ati okan ati ara nyin mo patapata li ailabuku.
Meter: 8.7.8.7.4.7.
Scripture: I Tes. 5:23
1
mfOrisun igbala kikun
Si sile fun gbogbo wa
Lat’ Odo Olugbala wa
Lo nsan yi gbogb’ aye ka;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.
2
mfIran ologo li eyi,
Isun iwenu ni o nsan,
crO nwe gbogbo abawon nu,
Ti idalebi ese,
O nsan sibe,
Eje ti nwe mo laulau.
3
mfIsun ijinle ife Re
Nsan ni inu okan wa;
crO nwe gbogbo ero aimo,
K’a le wa lailabawon,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.
4
mfIsun iye ainipekun,
Lati orun nsan si wa,
fOlorun dapo pelu wa,
Idapo t’odun julo;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.
5
fEru’banuje ti fo lo
Aniyan on ’yemeji,
Igbagbo ko beru ola
Tor’ Oluwa nsamona,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.