Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 685

Awon orun nsoro Ogo Olorun.

Meter: L.M.

Scripture: OD. 19:1

1

fTire, Oluwa, li ogbon,

Ododo mbe li odo Re,

Sibe niwaju ite Re,

Anu lo da owo Re ro.

2

Alale nfi ife Re han,

Ororo nf’ore nla Re han;

Ibinu Re ki tete ran,

Anu Re tan yi aye ka.

3

mfBaba, ore on ’toju Re

L’o fun wa n’iye on ’mole,

Ohun t’a ni, ohun t’a je,

Ebun atowo Re ni won.

4

mfOrisun ire, owo Re

L’o nseri ’bukun s’ori wa,

L’o nfonje on ayo fawon,

T’o wa loke, n’ile, l’okun.

5

fN’ipa Re ni gbogbo nkan wa

Agbara Re l’o gbe won ro;

Papa awon t’o ngb’ ore Re

Ti won ntapa si ’joba Re.

6

O pase ki orun k’o ran,

Bakanna, sori gbogb’ eda

Oro ojo ibukun Re

Sor’ eni ’re on buburu.

7

mpAwon t’o gan agbara Re

Y’o r’ina ibinu Re;

mfAwon t’o feran Re y’o ni

Ayo ati ade didan.

8

fTire, Oluwa, n’ijoba,

Tire ni gbogbo agbara;

Bi gbogbo eda tile ku,

Sibe ogo Re y’o ma tan.