Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 687

Kili emi o san fun Oluwa, nitori gbogbo ore re si mi.

Meter: 10.10.11.11.

Scripture: OD. 116:12

1

mfKini uno fi yin Olugbala mi,

Eni oloto t’o po l’or’-ofe,

T’o le fi igbala on irapada

F’awon onigbagbo t’o gb’okan won l’E?

2

fAyo eni t’a dande ti PO to,

Awon eniyan na t’o le yo n’nu Re!

Ayo won ni lati rin n’nu ’mole Re,

Sibe nwon nso nipa or’-ofe Jesu.

3

fWon nyo n’nu oko Re lojojumo;

Won nfododo Re s’ohun eto won;

Eje Re we won, n’nu ododo Re,

Laifoya ni nwon o yoju s’Olorun.

4

fIWO ni fuja, ogo, ipa won:

Emi si nreti igba ayo na,

Ti un o di atunbi, ti un o d’alaye,

Ojo ’gbala ti y’o gb’ori mi soke.

5

fJesu Oluwa, li abo fun mi;

Ko s’eni t’o le ja mi lodo Re;

Y’o se ohun gbogbo n’tor’ O feran mi

Olugbala mi y’o SO mi di otun.

6

ffO daju, Jesu, un o ri ’bukun Re,

Asiri Re si fere han fun mi;

Emi y’o ri ayo dipo ’banuje;

Un o n’ipin n’nu ayo awon t’O gbagbo.