Hymn 689
Oluwa, iwo ni mo gbe okan mi soke si.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 25:1
1
mpBaba, mo gb’okan mi si O
’WO ni mo gbekele;
crMo mo daju pe lodo Re
L’ebun pipe ti wa.
2
mfTire nikan l’anu, ore,
Agbara on Ogbon;
Li aisi Emi Omo Re
A ko le se ’re kan.
3
mpA ko s’oro rere kan,
A ko le ro ’re kan,
B’Iwo ko ba sure fun wa
N’tori Oluwa wa.
4
O f’eje Re ra or’-ofe,
Agbara eje na
L’o se ‘ranwo fun iran wa,
Ati fun mi pelu.
5
Gbogbo ise rere t’a nse,
Iwo li O nse won;
fTire n’iyin gbogbo ero
At’oro rere adura.
6
Lat’odo Re, nipa Jesu
L’a gb’ase adura;
N’nu eni ti a mbe laye;
Olodumare wa!