Hymn 690
Iwo li o da mi ni ide ninu iponju.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: OD. 4:1
1
mfBaba orun, Wo l’o mu wa
D’ojo oni f’alafia,
Pele l’Onto isise wa,
T’O si nf’iso Re so wa,
’Wo Ore at’ Amona wa,
A fe fi ope fun O;
A o se le yin O b’o ti ye
Fun ’fe Re ti ki pada?
2
mfNi gbogbo igba t’o koja
L’a nri anu gba lotun,
Itoju on iseun-ife
Ko fi igba kan jin na.
Ife ati aba orun;
Mba wa gbe tosan-toru
Ibukun t’a ko le siro
Ntan imole s’ona wa.
3
mpN’nu ’danwo nla l’a ti koja
Iji ’ponju ti lu wa;
Idamu ti sokun bo wa
Tobe t’a ko fi ri O;
mfSibe ife Re ko ko wa
Sibe n’nu ’banuje wa,
Iranwo t’a nse f’ara wa
Nipa agbara Re ni.
4
ppOpo awon olufe wa
Ti de opin ajo won;
Ara, omo ati ore.
Nwonaa lati pade wa
crNigba t'ajo wa ba pari,
Ti a si se alaisi,
mfBaba, mu wa la okun ja
Sinu ’mole ailopin.