Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 694

Ema ru eru omonikeji nyin.

Meter: S.M.

Scripture: Gal. 6:2

1

mfBukun ni fun ohun,

T’o de wa po n’nu ’fe;

Idapo awon olufe,

Dabi ijo t’orun.

2

mpNiwaju ’te Baba,

Li awa ngbadura;

Okan n’ireti at’eru,

Ati ni itunu.

3

pAwa mb’ara wa pin

Ninu wahala wa;

Awa si mb’ara wa sokun

Ninu ’banuje wa.

4

mfNigbat’ a ba pinya,

Inu wa a baje;

Sibe okan wa y’o j’okan

N’ireti ipade.