Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 697

Awa fe e, nitori On tete fe wa.

Meter: L.M.

Scripture: 1 Jn. 4:19

1

fAwa ko orin ife Re

Obangiji Oba Ogo;

Ko s'ohun ti lalasi Re,

Ola Re ko si nipekun.

2

fN’nu ife lo s’eda aye,

O da eniyan sinu re;

Lati inu s’akoso gbogbo;

ffE korin ’fe Eleda wa.

3

fLojojumo l’O ntoju wa,

O si mbo, O si nsike wa;

Beni ko gba nkan lowo wa,

ffKorin ’yin s’Onibu ore.

4

pO ri wa ninu okunkun,

Pe, a ko mo ojubo re;

N’if'e O fi ona han wa;

ffE korin ife Olore!

5

N’ife O fi Jesu fun wa,

Omo-bibi Re kan soso;

pOwa ra wa lowo ese;

ffA yin’fe Re Olugbala!

6

Ife Re ran oro Re wa,

Ife Re l’o si wa leti,

Ife Re si mu wa duro;

ffE korin ore-ofe Re.

7

Gbogbo eda kun fun’fe Re

Oluwa wa, Oba aye;

ffGbogbo agbaye, e gberin,

Orin ife Olorun wa.