Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 700

Olorun fe araiye to be ge ti O fi Omo bibi re kan soso fun ni.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: Jn. 3:16

1

fOlorun fe araye,

O fe tobee ge,

T’O ran Omo Re w’aye

T’O ku fun elese;

Olorun ti mo tele

pPe, emi o se si

Ofin ati ife Re;

IWO ha fe Mi bi?

2

Loto, Olorun fe mi,

Ani-ani ko si,

Awon t’o yipada si,

Igbala ni won ri:

ppWo! Jesu Kristi jiya,

Igi l’a kan a mo:

Wo! eje Re ti o nsan,

Wo! ro! Ma d’ese mo.

3

pJesu s’agbelebu Re,

Un o kan ese mi mo;

Labe agbelebu Re,

Un o we ese mi nu;

mfNigbat’ emi o ri O,

Ni orun rere Re,

ffNki yio dekun yin O,

F’ogo at’ola Re.