Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 702

Ki Kristi ki o le ma gbe inu okan nyin nipa igbagbo.

Meter: C.M.

Scripture: Efe. 3:17

1

mfJesu, kiki ironu Re

Fi ayo kun okan;

Sugbon k’a ri O l’o dun ju,

K’a simi l’odo Re

2

Enu ko so, eti ko gbo,

Ko t’okan jade ri:

Oko t’o s’owon, t’o dun bi

Ti Jesu Oluwa.

3

pIreti okan ti nkanu,

Ayo onirele

crO seun f’awon ti nwa O

fAwon t’o ri O yo.

4

fAyo won, enu ko le so

Eda ko le rohin;

Ife Jesu b’o ti po to

Awon Tire l’o mo.

5

fJesu, ’WO ma je ayo wa

’Wo sa ni ere wa

Ma je ogo wa nisiyi

Ati titi laelae.