Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 704

Oruko kan ti u bori gbogbo oruko.

Meter: C.M.

Scripture: Fili. 2:9

1

mfOruko kun mbe ti mo fe

Mo fe ma korin Re;

fIro didun ni l'eti mi,

Oruko didun ni.

2

mfO so ife Olugbala

T’O ku lati ra mi,

O so eje Re ’yebiye

Etutu elese

3

crO so ti iyonu Baba,

Ti O ni s’Omo Re,

O m’ara mi ya, lati la

Aginju aye ja.

4

fJesu, oruko ti'mo fe,

T’o si dun l’eti mi;

Ko s’eni mimo kan l’aye

T’o mo b’o ti po to.

5

Oruko yi j’orun didun

L’ona egun t’a nrin;

Yio tun ona yangi se

T’o lo s’od’Olorun.

6

Nibe pelu awon mimo

Ti won bo nin’ ese

fEmi o korin titun ni

T’ife Jesu si mi.