Hymn 709
Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan mi, ma si se gbagbe gbogbo ore Re
Meter: S.M.
Scripture: OD. 103:2
1
mfF’ibukun f’Oluwa
Yin ore-ofe Re.
fGbogb’ ohun ti mbe ninu mi
Yin oko Re mimo
2
mfF’ibukun f’Oluwa
Fun opo anu Re,
Mase gbagbe lati dupe
Inu’re Re si O.
3
crLoto, O mba ni wi
K’ise nigba gbogbo,
O nse suru, O si nlora
Lati binu si wa.
4
crO f’ese re ji O
O lora emi re,
O wo gbogbo arun re san,
O gba o lowo ’ku.
5
crO d’aso’ fe bo o,
Oro Re gbe o ro,
O SO agbara re d’otun
Bi ti eye idi,
6
fYin Oruko Re nla,
Eni t’O wo o san,
T’iseun ’fe Re de o l’ade,
F’ibukun f’Oluwa.