Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 711

Emi ogbon, ati oye

Meter: 8.8.6.D.

Scripture: Isa. 11:2

1

crEmi ogbon, to oju wa

Kuro ninu asan aye,

S’oto on ’fe orun;

Emi oye ti o daju,

Fi imole orun fun wa

Lati wa nkan toke.

2

crEmi ’moran, s’Amona wa

F’ijakadi aye ko wa.

K’a gba adet’orun;

mfEmi’gboya, k’agbara Re

Ran wa lowo nigba ’danwo

Pa wa mo lailese

3

crEmi imo, to ese wa

Li ona Re ti ko l’ewu

T’awon angel’ti rin;

Nibi t’Iwo Oluto wa,

mpIwo Emi ifokansin,

Mu wa sunm’ Olorun.

4

crSunmo wa l’ojo aye wa,

Emi iberu Olorun,

N’ikoko aya wa;

F’owo t’o ye kun okan wa

Lati sin ife mimo Re,

T’o l’ododo julo

5

mfMa to wa lo l’alafia,

Sinu iye ainipekun,

crK’a jere giga na;

K’ajaogun aye wa yi,

Nipa agbara Re mimo.

K’a si ba Krist’joba.