Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 713

Emi mo pe, ninu mi ko si nkan to dara.

Meter: 8.7.8.7.

Scripture: Rom. 7:18

1

mfBaba orun! emi fe wa

N’iwa mimo l’ododo:

Sugbon ife eran ara

Ntan mi je nigbagbogbo.

2

pAlailera ni emi se,

Emi mi at’ ara mi;

Ese ’gbagbogbo ti mo nda

Wo mi l’orun b’eru nla.

3

Ofin kan mbe li okan mi

’WO papa l’o fi sibe;

’Tori eyi ni mo fi fe

Tele ’fe at’ ase Re

4

Sibe bi mo fe se rere,

Lojukanna mo sina;

Rere l’oro Re i ma so;

Buburu l’emi si nse.

5

Nigba pupo ni mo njowo

Ara mi fun idanwo;

Bi a tile nkilo fun mi

Lati gafara f’ese

6

Baba orun, Iwo nikan

L’o to lati gba mi la;

Olugbala ti o ti ran,

On na ni un o gbamora.