Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 714

E je ki a maa sore fun gbogbo eniyan.

Meter: S.M.

Scripture: Gal 6:10

1

fOhun t’a fi fun O Tire ni, Oluwa;

Gbogbo ohun ti a si ni;

Owo Re l’o tiwa.

2

mfJe k’a gba ebun Re

Bi iriju rere;

Bi o si ti nbukun wa to,

Be l’a o fi fun O

3

pOpo ni ise n se,

Ti won ko r’ounje je

Opo l’o si ti sako lo,

Kuro l’agbo Jesu.

4

crK’a ma tu ni ninu,

K’a ma re ni ’lekun,

K’a ma bo alaini baba

N’ise t’a ba ma se.

5

mfK’a tu onde sile,

K’a mu asako bo,

Ka ko ni l’ona Olorun,

B’iwa Kristi l’o ri.

6

crA gba oro Re gbo,

diBusi igbagbo wa,

fOhun t’a se fun eni Re,

Jesu, ase fun O.