Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 719

Ongbe Olorun ngbe okan mi.

Meter: C.M.

Scripture: OD. 42:2

1

mpOlorun mi ’Wo l’emi mi!

Ki imole oro t’o la;

F’agbara Re han l’okan mi,

Ki O si mu mi l’ara ya.

2

diOngbe Re l’o ngbe okan mi

N’ile aginju gbigbe yi,

Ebi npa mi mo si daku,

cr’Fe Re nikan lo le yo mi.

3

IWO nikan l’okan mi nfe,

N’ile gbigbe yi, Olorun;

Mo fe ni ore-ofe Re

Ju gbogbo oro aye lo.

4

mfIfe Re t’o sowon julo

Y’o kun okan at’ahon mi,

Ogo, ayo alafia mi

Y’o je lati so iyin Re.

5

Gbogbo aye mi ni un o ma

F’orin ope ’bukun fun O;

Iyin t’o ye oruko Re

Ni un o ma gbe s’oke si O.

6

Oruko Re wa l’enu mi

At' ero mi, lor’ eni mi;

Mo n se asaro ise Re.

Pelu ’wariri l’oganjo.

7

Mo nri Owo Re n’nu ’se mi;

Nje un o korin titobi Re Olorun,

’WO t’O mu mi yo

Labe ojiji iye Re

8

fMo sun mo O timotimo;

Agbara Re y’o si gba mi

Low’aye at’ orun egbe

Igbala Re ki tase lae.