Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 720

Se alabapin pelu mi ninu iponju bi omo-ogun rere Jesu Kristi.

Meter: 8.7.8.7. & Ref.

Scripture: II Tim. 2:3

1

fE dide, omo igbala,

Eyin t’e fe Oluwa,

Dide, ilu alagbara

Ki ota to de Sion.

CHORUS

ffF’agbara re korin kikan,

Bi iro omi okun,

Nipa eje Kristi Jesu

Awa ju asegun lo

Awa ju asegun lo,

Awa ju asegun lo,

Nipa eje Kristi Jesu,

Awa ju asegun lo

2

crEgbe mimo ti igbani

Ti won ti nrin ona yi;

mfW’asia won t’o nfe lele,

Asegun nipa Kristi.

3

fA ti gbe ’ku mi ni ’segun,

lye wa mbe n’nu Kristi;

L’OJO ’farahan Oluwa

A o ho iho ayo.

4

fLaipe a o de’biite Re.

Ao si mo Oba Ogo;

Nibe a oke, “Kabiyesi”.

Gbogbo wa y’o gba ere.