Hymn 721
SO fun awon omo Israeli ki won ki o tesiwaju
Meter: 11.11.11.11. & Ref.
Scripture: Eks. 14:15
mfE ma te siwaju, Kristian ologun,
Ma tejumo Jesu t’O mbe niwaju,
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo! Asia Re wa niwaju ogun,
ffE ma te siwaju, Kristian ologun
Sa tejumo Jesu t’O mbe niwaju
fNi oruko Jesu, ogun esu sa,
Nje Kristian ologun ma nso si isegun
crOrun apadi mi ni hiho iyin,
Ara, gb’ohun yin ga, gb’orin yin soke
fBi egbe ogun nla n’Ijo Olorun,
diA ra, a n rin l’ona t’awon mimo nrin;
mfA ko ya wa ni ’pa, egbe kan ni wa.
Okan ni ’reti, ni eko ni ife
Ite at’ijoba wonyi le parun,
Sugbon Ijo Jesu y’o wa titi lae,
crOrun - apadi ko le bor’ ijo yi,
A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.
fE ma ba mi kalo, eyin eniyan,
D’ohun yin po mo wa, l’orin isegun;
crOgo, iyin, Ola fun Kristi Oba!
Eyi ni y’o maje orin wa titi.