Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 722

Iwo ti fi opagun fun awon ti o beru Re.

Meter: 11.11.11.11. & Ref.

Scripture: OD. 60:4

1

fDidan l’opagun wa, o ntoka s’orun!

On f’ona han ogun si ile t’orun!

B’a ti nlo l’aginju, l’a nf’ayo gbadua

Pel’okan isokan l’a m’on’ orun pon.

CHORUS

Didan l’opagun wa, O ntoka s’orun,

O nf’ona han ogun si ile t’orun.

2

mfJesu Oluwa wa, l’ese mimo Re

Pelu okan ayo l’Omo Re pade,

pA ti fi O sile, a si ti sako,

To wa Olugbala, si ona toro.

3

mfJesu apere wa, ’WO S’Omode ri,

Se wa l’omo rere, k’a n’iwa pele,

crLi akoko ewu, nibo l’a ba re?

B’o ye li odo Re, Olugbala wa.

4

fTO wa l’ojo gbogbo l’ona t’awan to,

Mu wa nso s’isegun l’ori ota wa;

diK’angeli Re s’asa wa ’gb’oj’orun su

pDariji, si gba wa l’akoko iku.

5

fA ba le pe l’awon angeli l’oke

Lati jumo ma yin n’ite ife Re:

cr’Gbat’ ajo wa ba pin, isimi y’o de;

ffAt’alafia, at’orin ailopin.