Hymn 723
Sugbon eyi ti enyin ni, e di i mu sinsin titi Emi o fi de.
Meter: 8.5.8.5. & Ref.
Scripture: Ifi. 2:25
1
fHa! egbe mi e w’a si a
Bi ti nfe lele!
Ogun Jesu fere de na,
A fere segun.
CHORUS
ff“D’odi mu, Emi fere de”
Beni Jesu nwi,
Ran ’dahun pada s’orun, pe
“Awa o di mu.”
2
fWo opo ogun ti mbo wa;
Esu nko won bo;
Awon alagbara nsubu,
pA fe damu tan!
3
fWo asia Jesu ti nfe,
Gbo ohun ipe;
A o segun gbogbo ota
Ni oruko Re
4
fOgun ngbona girigiri,
Iranwo wa mbo;
Balogun wa mbo wa tete,
Egbe, tujuka!