Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 725

E je alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipa Re.

Meter: S.M.

Scripture: Efe. 6:10

1

fOmogun Krist’ dide,

Mu ’hamora yin wo;

Lo ipa t’Olorun fun yin,

Nipase Omo Re.

2

crGbe ’pa Olorun wo,

T’Oluwa om’ ogun,

Eni t’o gbekele Jesu,

O ju asegun LO

3

mfNinu ipa Re nla,

O ni ki E duro,

Tori k’e ba le jija na,

E di ’hamora yin.

4

crLO lat’ ipa de ’pa

Ma ja, ma gbadura;

Te agbara okunkun ba,

E ja, k’e si segun.

5

Leyin ohun gbogbo,

Leyin gbogbo ija,

K’e le segun n’ipa Kristi

K’e si duro sinsin.