Hymn 726
Awon ogun orun si nto O lehin.
Meter: C.M.
Scripture: Ifi. 19:14
1
fOmo Olorun nip s’ogun,
L’ati gb’ade Oba;
Opagun Re si nfe lele.
Ta lo ’s’om’ ogun Re?
2
mpEni t’o le mu ago na,
T’o le bori ’rora,
crT’o le gbe agbelebu Re,
fOn ni om’ ogun Re
3
mfAjeriku ti o ko ku,
T’o r’orun si sile;
T’o ri Oluwa Re loke,
T’o pe k’O gba On la.
4
diPelu idariji l’enu
Ninu ’rora iku,
crO bebe f’awon t’o np’a lo,
fTani le se bi Re?
5
ffEgbe mimo; awon wonni;
T’Emi Mimo ba le,
Awon akoni mejila;
Ti ko ka iku si.
6
fWon f’aya ran ida ota,
Won ba eranko ja,
diWon f’orun won lele fun’ku
Tani le se bi won?
7
ffEgbe ogun t’agba t’ewe,
L’okunrin l’obinrin
Won y’ite Olugbala ka.
Won wo aso funfun.
8
fWon de oke orun giga,
diN’nu ewu on 'ponju:
pOlorun fun wa l’agbara
Ki a le se bi won.