Hymn 727
Ma aja ija rere ti igbagbo.
Meter: C.M.
Scripture: 1 Tim. 6:12
1
mfAjagun Jesu J’emi bi?
At’omo ehin Re?
Un o ha beru lati wasu
Agbara isin Re?
2
mfAo ha gbe mi soke orun
Lori busun rorun,
’Gbati opo ja f’ere na
Lori okun eje
3
Ko ha s’ota lati ba ja?
Un o ha ko ’gbi lile?
Aye ha fe ore-ofe
T’y’o mu mi d’odo Re?
4
Mo ni ja, bi un o ba joba,
pRan ’gboya mi lowo!
Un o f’ara da gbogbo ise
Pelu iranwo Re