Hymn 73
Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo
Meter: C.M
Scripture: OD 34:1
1
mfN’nu gbogbo ayida aye
Ayo on wahala;
CrIyin Olorun ni y’o ma
Wa l’enu mi titi
2
fGbe Oluwa ga pelu mi,
Ba mi gb’oko Re ga:
MpN’nu wahala, ‘gba mo ke pe
FO si yo mi kuro
3
Ogun Olorun wa yika
Ibugbe Oloto;
Eniti o ba gbekele,
Yio ri igbala
4
mfSa dan ife Re wo lekan
‘Gba na ‘wo o mo pe,
Awon t’o di oro Re mu
Nikan l’eni ‘bukun
5
mfE beru Re, eyin mimo,
Eru miran ko si;
CrSa je ki ‘sin Re j’ayo yin
FOn y’o ma tojun yin