Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 732

Sugbon ohunkohun ti o jasi ere fun mi, awon ni mo ti kasi ofo nitori Kristi

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: Fili. 3:7

1

Jesu, mo gb’agbelebu mi

Ki nle ma to O leyin;

Otosi at’eni egan,

’WO l’ohun gbogbo fun mi

Bi ini mi gbogbo segbe

Ti ero mi gbogbo pin

Sibe, oloro ni mo je!

T’emi ni Krist’ at’orun.

2

Eda le ma wahala mi,

Y’o mu mi sunmo O ni;

Idanwo aye le ba mi,

Orun o mu ’simi wa,

Ibanuje ko le se nkan

Bi ’fe Re ba wa fun mi;

Ayo ko si le dun mo mi

B’iwo ko si ninu re

3

Okan mi, gba igbala re;

Bori ese at’eru;

F’ayo wa ni ipokipo,

Ma sise lo, ma weyin,

Ro t’emi t’o wa ninu Re

At’ ife Baba si o!

W’Olugbala t’O ku fun o

Omo orun mase kun.

4

Nje koja lat’ore s’ogo

N’nu adura on ’gbagbo;

Ojo ailopin wa fun O,

Baba y’o mu o de ’be,

Ise re l’aye fere pin

Ojo ajo re nbuse,

Ireti y’o pada ’sayo,

Adura s’orin iyin.