Hymn 734
Omo, lo loni ninu ogba ajara mi.
Meter: 8.7.8.7. & Ref.
Scripture: Mat. 21:28
1
mfGbo bi Oluwa ti mbebe,
Ise wa fun gbogbo wa;
crGbo bi Emi ti nwi pelu,
Je ipe na bayi pe:
CHORUS
f“Mo setan lati sise fun O Jesu,
Emi de, ran mi;
crMo nfe lati se ife Re ni pipe,
Un o lo s’ibit’O ba ran mi
fMo setan lati sise fun O Jesu
Emi de, ran mi;
Bi ona tile sokun, eru ko bami
Mo se tan fun ise Jesu.
2
crOhun kan npe o nisiyi,
Fi eti si ohun na;
mpO n so si o l’eti jeje,
Je ipe na bayi pe.
3
diOkan pupo nku n’nu ese,
Yara lati se ’ran wo;
’Tori akoko nkoja lo,
So fun Jesu bayi pe.