Hymn 742
E ma ni igbona okan, e ma sin Oluwa.
Meter: 8.8.6.D.
Scripture: Rom. 12:11
1
mfJesu inu wa ti dun to,
Pe, a je omo eyin Re;
Awa t’a nf’aye wa
Gbo t’Olorun ati t’eda,
A n f’osan se ise rere
A n f’oru gbadura.
2
crA ko r’aye fun iroju,
Tabi fun imele sise;
Awa nte siwaju;
Are ara ko si rara,
F’eni ti o nsin Olorun
T’o mo Iwo nikan.
3
mfT’ojo, t’erun l’o nyara lo,
Akoko na ko to fun wa
Lati korin ’yin Re,
Wakati ayo na ko to,
A fedapo m’ogun orun
Korin ayeraye.
4
mfAwa nfe lati ma yin O,
crPelu awon ogun orun;
fAwon egbe didan
diTi nke Mimo, Mimo, Mimo!
fK’a ma korin y’ite Re ka,
ffOrin ayeraye.