Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 745

E ya Barnaba on Saulu soto fun mi fun ife ti mo ti pe won si.

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: Ise A. 13:2

1

mfGbo ohun Jesu ti nke pe;

“Tani y’o sise loni;

Oko pon pupo fun ’kore;

Tani y’o lo ko wa ’le?”

crKikankikan l’Oluwa npe,

Ebun nla ni y’O fun o,

Tani y’o fi ayo dahun

fPe: “Emi ni yi; ran mi?

2

mfB’iwo ko le la okun lo

Lati w’awon keferi;

O le ri won nitosi re,

Nwon wa l’enu ona re;

B’o ko le fi wura tore,

Ebun miran ko kere,

Die t’o si se fun Jesu,

’Yebiye ni l’oju Re.'

3

mpB’iwo ko le se alore

L’ori odi Sioni

Lati t’oka s’ona orun;

pLati fiye lo eda;

’Wo le f’adura at’ore

Se ohun t’Olorun wi;

cr'Wo le se gege bi Aaron!

T’o gb’owo woli soke.

4

mfMa je k’a gbo ki o wipe,

Ko si nkan t’emi le se!

Nigbat’ emi eniyan nku

Ti Oluwa si npe O,

F’ayo gba ise t’O ran o,

F’ise Re se ayo re;

ff’Gba t’o npe o, tara dahun

Pe: emi ni yi; ran mi!