Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 747

E ma ronu awon nkan ti mbe loke, ki i se awon nkan ti mbe li aiye:

Meter: L.M.

Scripture: Kol. 3:2

1

mfOlugbala, jo sokale!

F’or’-ofe Re ran mi l’owo;

Yo ife aye l’okan mi.

Pese aye fun ara Re.

2

Fi ara Re kun emi mi

Ki O si so mi d’ominira!

’Ko fe le ’pa ohun miran

Bikose ’WO losan l’oru.

3

Niwon ’gbati mo wa l’aye

Nki 'o'lepa ire miran;

Emi y’o dagbere f’aye,

Pelu gbogbo itanje re.

4

Ona t’Olugbala mi rin,

Ni uno f’iyara wa kiri;

Beeli emi ki o si mo

Ife miran leyin Tire.

5

fLat’oni lo, k’adun aye

Ma ri ibi gba l’okan mi;

Se ni Tire, eto Re ni,

IWO n’ise Oluwa re.

6

Oro, ola afe asan

Ti aye yi le fifun ni;

Okan mi ko gbogb’ etan yin

Kristi nikan ni y’o ma sin.

7

fIWO nikan ni mo le fe;

Pelu ife atinuwa;

Ayo wol’otobi toyi

Pe, IWO gba mi ni Tire!

8

Ko s’ohun ti mo fe l’aye

Ju k’ife Re wa l’aya mi;

Eyiyi sa ni mo ntoro,

Mo ko ohun gbogbo ’yoku.