Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 754

Ni igbona okan, e ma sin Oluwa.

Meter: 8.8.8. D.

Scripture: Rom. 12:11

1

mpOluwa, wo iranse Re!

Mas’ aifi oju Re to mi,

crKi ngbo, ki npa Oro Re mo,

Ki nwadi, ki nsi se ’fe Re,

Ki nma se gbekele ’se mi,

Sugbon ki nmu ododo se

2

mpB’ or’-ofe Re ba je lo mi,

Emi eni ainilari,

crYan ’se on akoko fun mi,

Jeki nso eso ninu Re;

Jeki ns’ise mi pelu Re,

Si ba mi se li asepe.

3

pAilera ni gbogb’ ero mi,

Se b’o ti ye li oju Re;

crJesu, ki’se mi je Tire!

Oluwa, pipe n’ise Re.

O si to loju Baba Re;

Rere ni gbogbo ise Re

4

crMo fara mi le O lowo;

Se mi b’o ti to loju Re!

Fi ami Re si ara mi,

Si jeki nmu Oro Re se.

mfKi nsin O pelu okan kan,

Ki nwa, ki nku fun ogo Re