Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 760

Enu bode mejeji lajo pearli mejila

Meter: 8.7.8.7.D. & Ref.

Scripture: Ifi. 21:21

1

M o fi won sile fun Jesu

Aye asan ko je nkan:

crGbogbo adun re bi egbin,

Gba mba ranti Kalfari;

B’ore tile ko mi sile,

Ti o ku emi nikan;

mfMo l’ore kan to wa n’tosi

Nigba ’lekun pearl ba si

CHORUS

mpAye yi yo rekoja,

Orun re yoo si wo;

fNko ni mo ’banuje mo

Nigba ’lekun pearl ba si.

2

mf’Gba mo gbohun Jesu to npe,

At’ipejeje angel,

Un o ro mo Olugbala mi

La afonifoji ja;

Un o d’ileri Re owon mu

To ju oro ayejo,

f“Maberu, un o wa pelu re

Nigba ’lekun pearl ba si”.

3

mfNi ikoja odo Jordan,

At’afefe tutu Re:

N’igi iye, aiku ngbile

Ti omi iye si nsan;

N’ile ayo awon mimo

N’isura ainiye wa,

Awon angeli si nduro

Nibi ’lekun pearl si’le.