Hymn 761
O fiwaju won, awon agutan si nto lehin
Meter: L.M. & Ref.
Scripture: Jn. 10:4
1
mpO na t’O yan l’emi o to,
’Tori mo gbeke mi le E,
Mo ranti pe nitori mi
Ni O se ku ni Kalfari
CHORUS
mfJesu nto mi l’osan l’oru
Jesu nto mi l’ona gbogbo
O je Ore toto fun mi,
Tori mo ranti Kalfari.
2
Mo ti feran ase Re to;
Mo fe k’owo Re ma to mi,
crIfe rere Re ti dun to
T’O fihan l’oke Kalfari.
3
fMo nlo pel’okan diduro
Ninu Kristi Olugbala;
Ni igbekele pe laipe
Uno ri Jesu ti Kalfari.