Hymn 764
Nitori Emi ni Olorun re: Emi yoo fun o ni okun
Meter: C.M. & Ref.
Scripture: Isa. 41:10
1
mfE mi ko le sai l’agbara,
Lati j’olododo;
Tori Olorun mbe fun mi,
Lati ran mi lowo.
CHORUS
crA! mba le gbeke mi le E
Bi On ti wa nitosi,
mfOn ko ni sai ran mi l’owo
Y’O si pese f’aini mi.
2
mfNko le sai ma l’ore toto
Jesu ni ore mi;
crB’ore miran ko tile si,
Jesu fe mi d’opin.
3
Nko le sai ma l’ayo giga,
Ayo Re wa n’nu mi,
Kukuru ni ayo t’aye,
Tire wa titi lae
4
mfNko le sai ma l’ohun gbogbo,
Olorun je gbogbo;
Mo nkorin ’yin Re lojojo,
Mo npe oruko Re.