Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 767

A WON ogun ti mbe li orun si nto lehin

Meter: 9.8.9.7. & Ref.

Scripture: Ifi. 19:14

1

mfGbo iro li opopo aye

Bi ti igbi omi okun,

Ti nfi agbara re ru s’oke

T’o si nkolu ebute.

CHORUS

Gbo iro ese omo ogun

Bi won ti nrin lo li ona na,

Are mu won fun ’se at’irin ajo

Ati ija kikoro;

Sugbon won gbagbo, won tejumo

Ona na t’awon mimo ti nrin,

Bi won ti nlo ni ’gbagbo

Won ndagba n’nu Olorun Alaye

2

Won ntesiwaju pelu ’gbagbo

Ti ekokeko ko le mi;

Won gbagbo pe oro Olorun

Le pese faini gbogbo.

3

crDapo mo won, aye wa sibe,

Duro de ’bukun Olorun;

Oun ni ’reti gbogbo agbaye

Lati sise ododo.