Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 771

O si wi fun won pe: e ma to mi lehin, lojukanna nwon si nto O lehin.

Meter: 8.7.8.7

Scripture: Mat. 4:19 & 20

1

mfJesu npe wa l’osan, l’oru

Larin irumi aye;

crLojojumo la ngb’ohun Re

pWipe, “Kristian, tele mi”.

2

mfAwon Apostel igbani

Ni odo Galili ni;

Won ko ile, ona sile,

Gbogbo won si nto leyin.

3

Jesu npe wa kuro ninu

Ohun aye asan yi;

Larin afe aye O nwi;

pPe: “Kristian, e feran Mi”.

4

mfL’arin ayo at’ekun wa,

L’arin lala on ’rorun:

Tantan l’O npe l’ohun rara

pPe: “Kristian, e feran Mi”.

5

mpOlugbala, nip’anu Re,

crJe ki a gbo ipe Re;

F’eti ’gboran fun gbogbo wa,

K’a fe O ju aye lo.