Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 781

Enikeni ti o ba tiju mi, Omo eniyan yio tiju re pelu.

Meter: L.M.

Scripture: Mk. 8:38

1

mfJesu, O hale je be pe

pKi eni kiku tiju Re

Tiju Re, ’Wo t’angeli nyin,

Ogo Eni nran titi lae.

2

Ki ntiju Jesu! O san pe

Ki ale tiju irawo;

Oun ni ntan imole orun

Sinu okan okunkun mi.

3

Ki ntiju Jesu! bakanna

Je ki oru tiju osan;

Okun oru bo okan mi

K’irawo oro to tuka.

4

Ki ntiju Jesu! Ore ni,

Eni mo nwo lati d’orun!

B’o ba ri be, k’oju ti mi,

Pe nko b’owo foko Re mo

5

Ki ntiju Jesu! mo le se,

Bi nko ba l’ese t’ao wenu,

Ti nko l’edun, ti nko l’eru,

Ti nko fe ’re tab’igbala.

6

Un o ha hale lasan n’gbana

Pe mo l’Olugbala t’a pa

fA! k’eyi je isogo mi

Pe: Kristi ko si tiju mi