Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 782

Awon eni irapada Oluwa yio pada, nwon o wa si Sioni ti awon ti orin.

Meter: 15.9.15.9. & Ref.

Scripture: Isa. 35:10

1

mfO ti dun to lati mo Jesu

Eni t’O gba mi la,

’Jojumo Okan mi kun f ayo,

Ayo ni lati ri pe O mba ihi lo sibikibi,

’Jojumo ogo ni f’Oluwa.

CHORUS

fO ti dun to lati ma ba rin,

O ti dun to lati ma ba rin,

Y’O ma se amona mi

N’nu ’mole at’okunkun;

O ti dun to lati ma ba rin.

2

mfO ti dun to ki O wa nitosi nigba idanwo,

Ka sa gbagbo ka si gbadura;

O ti dun to ki a ma gbe n’nU

Kristi nigbakugba

Y’O ma fi ogo orun kun wa.

3

mfY’o ti dun to lati pade Re l’ebute ogo na

Awa yo pade l’aipinya mo;

Orin ogo, ogo, ogo la o ma ko titi lae

Ni ilu ologo ti Baba.