Hymn 783
Iyin Oluwa yio ma wa li enu mi titi lae.
Meter: L.M.
Scripture: OD. 34:1
1
mfOlorun, gbogbo ojo mi
L’emi o fi ope yin O;
Orin mi yo ba ’mole ji,
Yo mu okun oru tuka.
2
mpB’aniyan fe ba ’simi je
T’edun fe ba mi n’inu je,
mfOrin iyin Re t’emi nko
Yo ko ’kedun na n’ijanu.
3
mp’Gba ’ku ba bori ara mi,
Ti gbogbo ipa ede pin;
fOju mi yo kun fun ayo
At’ope t’emi ko le so.
4
Sugbon ’gbat’ija ’keyin tan
T’ago ara ba bo sile;
Tayotayo ni un o goke
Lati gbe orin ti orun.
5
fEmi o ko orin giga
Ti ndun larin ode orun:
Em’o f’ayo to apere
Awon angel to y’ite ka.
6
fUno ma sin O tayotayo,
Bi emi mi yo ti wa lae;
Ise didun, orin giga,
Yo je ipin ayeraye.