Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 784

Sugbpn awon ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara Won se.

Meter: L.M.

Scripture: Isa. 40:31

1

mfJi, okan wa, k’eru wa lo;

Ki ero ijaya wa lo;

Ji, ko sure ije t’orun,

Ko si gbe ’gboya ayo WO.

2

Loto, ona na kun f’egun

Are si mu emi eniyan;

Sugbon won gbagbe Olorun

Ti n f’agbara bo eniyan Re.

3

Olodumare, ipa Re

Leke, o mbe l’otun titi,

Sinsin lo duro, bi odun

Ti nyipo li ainipekun.

4

Lodo Re n’isun na ti nsan

L’okan wa yo ma mu, titi

Gba’won to gbekele’pa won

Yo yo danu, yo re, yo ku.

5

B’idi ti nyara fo l’orun

Lao goke lo s’ibugbe Re;

Okan wu yo fiye ’fe fo

Laise are lona orun.