Hymn 785
Ki emi ki o le ma wo ewa Oluwa ki emi ki o sifi inu didun wo tempili Re.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 27:4
1
Ohun kan ni un o ma lepa
Pelu gbogb’emi mi;
Oluwa, se fun ’ranse Re
Ohun t'Emi Re fe
2
diFun mi n’ipo ni ile Re
Larin awon mimo;
Ki nle ma wo oju Re lae,
Ki nwole lese Re
3
mpE wa oju Mi! B’o ti wi,
L’aise ijafara
L’okan mi f’ayo dahun pe:
crUn o ma wa oju Re!
4
diMa ko mi b’ibanuje de,
T’adun aye fo lo;
’Gbat’ obi on ara ko mi,
Olorun, ranti mi.
5
mpNigbakugba ni mo ndaku,
Ti nko si ni ’reti;
Sugbon 'ponju mu mi ranti
Ore Re atijo.
6
mfF’igboya duro d’Oluwa
Emi mi, ye beru;
Onidajo ododo mbo,
Irapada re de.