Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 789

Emi kojefi O sile, beni Emi ko je ko o sile

Meter: 7.6.7.6.6.6.6.5. & Ref.

Scripture: Heb. 13:5

1

mpIba j’afonifoji

’Bit’opo ewu wa:

Iba je ninu ’mole

Ti mo wal’alafia;

Ohun kan yi daju;

mpB’okunkun tile su,

mfBi Jesu pelu mi

Ko s’ewu nibe

CHORUS

mfBijesu pelu mi,

Un o lo ’bikibi;

Ibiti mo ba wa orun lo je

B’O wa nibe!

Anfani ni lati ru agbelebu Re

Bi Jesu pelu mi

Ko s’ewu nibe

2

A le ran mi lo lati

Kede oro iye

Fun awon ti o sonu,

Ti npafo n’nu ese.

Ohunkohun to de,

Nipa Igboran yi

Bi Jesu ba mi lo

Ko s’ewu nibe.

3

mfB’Oluwa pe mi lati

Se ise nitosi

Nigbati opo nsise

Fun Un l’ona jinjin;

Un o fi ’gbagbo mi han

N’nu 'dajo Re gbogbo;

Bi On duro Timi,

Ko s'ewu nibe.

4

mfKi ise fun mi lati

Yan l’Oluwa lowo;

Temi ni'lati lo si

Ibit’O ndari mi;

Ibit’O wu ko je,

Nihin tabi lohun,

Un o wa pelu Jesu

Ni itelorun.