Hymn 795
Sugbon emi nlepa nso.
Meter: C.M.
Scripture: Fili. 3:12
1
mfT’Olorun ni emi yo se
Ni gbogbo ona mi;
B’aye tile dide si mi,
Krist’ yo j’aworan mi.
2
T’Olorun ni emi yo se,
mpBi ogun tile nja;
’Gbat’ara, ore ba KO mi,
mfBaba yo di mi mu.
3
T’Olorun ni emi yo se
L’ero at’iwa mi;
Ninu oro tabi ’ponju,
Jesu yo s’asa mi.
4
Ninu idamu aye yi,
L’emi yo ro mo O;
F’owo Otun ododo Re
Gb’ emi omo Re ro.