Hymn 796
E lakaka lati wo oju ona koto.
Meter: L.M.
Scripture: Lk. 13:24
1
mfE mi nlepa l'ojojumo,
Mo si tun nlakaka pelu;
Ki nle jogun ibugbe na
Ti Jesu ti pese fun mi.
2
mfEmi nnoga l’ojojumo,
Lati ri pe owo mi te
Ade ologo ti ndan ni;
T’a se l’oso fun ayanfe
3
mfEmi nreti l’ojojumo
Lati gbo ohun ayo ni,
Gbati mba siwo ise pe:
“Bo sinu ayo Baba re.
4
crB’aye tabi awon ore
Ba fe fa mi s’ona egbe,
Jeki nle f’igboya so pe:
fT’em’ni Jesu, un o ba rele.
5
cr’WO Oluwa Olorun mi,
Mu mi Segun eran ara,
K’emi ma ba kose, subu
Kuro lona ile ogo.