Hymn 797
Gbo adura mi, Oluwa.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 102:7
1
mpBaba alanu t’o fe wa,
Mo gb’okan mi si O;
mfIpa Re t’o po l’o gba wa;
Awa nkorin si O.
2
fTire papa l’awa fe se,
Gb’okan wa fun ebo;
O da wa, osi tun wa bi,
A fara wa fun O.
3
Emi Mimo, wa sodo mi,
Fife Oluwa han;
Fun mi k’emi k’o le ma rin,
N’ife Oluwa mi.