Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 799

A la bukun, fun ni eyin ti n fonrugbin niha omi gbogbo.

Meter: 8.7.8.7. & Ref.

Scripture: Isa. 32:20

1

fA ra mi fun ’rugbin rere,

Nigba ifunrugbin wa,

Ma sise l’oruko Jesu,

Tit ’Oun o tun pada wa,

CHORUS

ffNigbana ni a o f’ayo ka a,

Olukore a ko won si aba.

2

fOlugbala pase wipe,

Sise nigbat’o j’osan;

Oru mbowa, mura giri,

Oloko fere de na.

3

T’agba t’ewe jumo ke, pe,

’Wo l’oluran lowo wa;

Mu ni funrugbin igbagbo,

K’a s’eso itewogba.

4

mfLala ise fere d’opin,

Owo wa fe ba ere;

B’O de ninu olanla Re,

Y’o so fun wa pe, “siwo”.