Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 801

To Omode li ona ti yio to.

Meter: C.M.

Scripture: Owe 22:6

1

mfOlorun ogbon at’ore,

Tan ’mole oto Re,

Lati fona toro han wa,

Lati to sise wa

2

mfLati to wa koja larin

Apata l’agbami;

K’oko wa le rin laisewu,

K’agunle l’alafia.

3

mfOre-ofe Re l’o ko wa

B’a ti ko elomi,

A fe to awon omo wa

Ni gbogbo ona Re.

4

mpIfekufe on ’gberaga,

K’a pa run ninu won;

K’a fi ona mimo han won,

Si Olugbala won.

5

mfK'a ma wo O nigbakugba

Fun apere lati

Ko won n’iberu on ’reti;

Fun won l’ero pipe.

6

mfK’a fitara pele ko won

Lati ma se ’gboran;

K’a ma fikanra se ohun

Ti a ba fife se.

7

crEyi l’a figbagbo bere,

Ogbon lat’ oke wa!

Ti y’o feru omo kun won,

Pelu ife mimo.

8

diK’afa’fewon kuro l’afe;

K’ama fibi bo won;

K’a jeki okan odo won

Te sodo Olorun.