Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 803

Oju Oluwa mbe nibi gbogbo.

Meter: C.M

Scripture: Owe. 15:3

1

mfIse gbogbo ti awa nse,

Ni Olorun ti ri;

Ero gbogbo t’o wa ninu,

Ni Olorun si mo.

2

mpA ko le f’ese wa pamo,

Gbogbo won l’O ti mo:

A npuro, a ntan ’ra wa je,

B’a ro pe ko mo won.

3

Ohun gbogbo han ni gbangba,

Ni oju Olorun;

Okunkun ati imole,

Si ri bakanna fun.

4

fOlorun, je k’a ranti pe,

Oju re si ri wa;

Si je ki awa k’o beru'

Lati dese si O.