Hymn 805
Emi ni Alfa ati Omega, li Oluwa wi.
Meter: 8.8.8.5. & Ref.
Scripture: Ifi. 1:8
1
mfMo fi gbogbo okan mi tan
Eni t’O le gb’emi mi la,
Abo nla, ti ki ye lae
fOro Re daju.
CHORUS
fEmi l’Alfa, at’Omega,
Ipilese ati opin,
Ti O wa, t’O ti wa,
Ti O si mbo wa,
Emi l’Alfa, at’Omega,
Ipilese ati opin
Olodumare, Olodumare”
L’Oluwa wi.
2
fOkan mi nso pelu ayo.
Ti Eni ti ngbe inu mi,
If’ eni ti nteloro Re.
Lati mu duro.
3
crJehofa, Olorun, gba mi
Lowo ’yemeji at’eru;
Fi ’gbagbo gbigbona fun mi,
M’okan mi duro.